Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 63:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN, iwọ li Ọlọrun mi; ni kutukutu li emi o ma ṣafẹri rẹ; ongbẹ rẹ ngbẹ ọkàn mi, ẹran-ara mi fà si ọ ni ilẹ gbigbẹ, ati ilẹ ti npongbẹ, nibiti omi kò gbe si.

2. Bayi li emi ti wò ọ ninu ibi-mimọ́, lati ri agbara rẹ ati ogo rẹ.

3. Nitori ti iṣeun-ifẹ rẹ san jù ìye lọ, ète mi yio ma yìn ọ.

4. Bayi li emi o ma fi ibukún fun ọ niwọnbi mo ti wà lãye: emi o ma gbé ọwọ mi soke li orukọ rẹ.

5. Bi ẹnipe ijà ati ọ̀ra bẹ̃ni yio tẹ ọkàn mi lọrun; ẹnu mi yio si ma fi ète ayọ̀ yìn ọ:

Ka pipe ipin O. Daf 63