13. Ṣugbọn iwọ ni, ọkunrin ọ̀gba mi, amọ̀na mi, ati ojulumọ mi.
14. Awa jumọ gbimọ didùn, awa si kẹgbẹ rìn wọ̀ ile Ọlọrun lọ.
15. Ki ikú ki o dì wọn mu, ki nwọn ki o si lọ lãye si isa-okú: nitori ti ìwa buburu mbẹ ni ibujoko wọn, ati ninu wọn.
16. Bi o ṣe ti emi ni, emi o kepè Ọlọrun; Oluwa yio si gbà mi.
17. Li alẹ, li owurọ, ati li ọsan, li emi o ma gbadura, ti emi o si ma kigbe kikan: on o si gbohùn mi.
18. O ti gbà ọkàn mi silẹ li alafia lọwọ ogun ti o ti dó tì mi: nitoripe pẹlu ọ̀pọlọpọ enia ni nwọn dide si mi.
19. Ọlọrun yio gbọ́, yio si pọ́n wọn loju, ani ẹniti o ti joko lati igbani. Nitoriti nwọn kò ni ayipada, nwọn kò si bẹ̀ru Ọlọrun.
20. O ti nà ọwọ rẹ̀ si iru awọn ti o wà li alafia pẹlu rẹ̀: o ti dà majẹmu rẹ̀.
21. Ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ kunna jù ori-amọ lọ, ṣugbọn ogun jija li o wà li aiya rẹ̀: ọ̀rọ rẹ̀ kunna jù ororo lọ, ṣugbọn idà fifayọ ni nwọn.
22. Kó ẹrù rẹ lọ si ara Oluwa, on ni yio si mu ọ duro: on kì yio jẹ ki ẹsẹ olododo ki o yẹ̀ lai.
23. Ṣugbọn iwọ, Ọlọrun, ni yio mu wọn sọkalẹ lọ si iho iparun: awọn enia ẹ̀jẹ ati enia ẹ̀tan kì yio pe àbọ ọjọ wọn; ṣugbọn emi o gbẹkẹle ọ.