6. Emi ti nkepè ọ, nitori pe iwọ o gbohùn mi, Ọlọrun: dẹ eti rẹ si mi, ki o si gbọ́ ọ̀rọ mi:
7. Fi iṣeun ifẹ iyanu rẹ hàn, iwọ ti o fi ọwọ ọtún rẹ gbà awọn ti o gbẹkẹle ọ là, lọwọ awọn ti o dide si wọn.
8. Pa mi mọ́ bi ọmọ-oju, pa mi mọ́ labẹ ojiji iyẹ-apá rẹ,
9. Lọwọ awọn enia buburu ti nfõró mi, lọwọ awọn ọta-iyọta mi, ti o yi mi kakiri.
10. Nwọn fi ọ̀ra sé aiya wọn, ẹnu wọn ni nwọn fi nsọ̀rọ igberaga.
11. Nwọn ti yi wa ká nisisiyi ninu ìrin wa; nwọn ti gbé oju wọn le ati wọ́ wa silẹ:
12. Bi kiniun ti nṣe iwọra si ohun ọdẹ rẹ̀, ati bi ọmọ kiniun ti o mba ni ibi ìkọkọ.
13. Dide, Oluwa, ṣaju rẹ̀, rẹ̀ ẹ silẹ: gbà ọkàn mi lọwọ awọn enia buburu, ti iṣe idà rẹ:
14. Lọwọ awọn enia nipa ọwọ rẹ, Oluwa, lọwọ awọn enia aiye, ti nwọn ni ipin wọn li aiye yi, ati ikùn ẹniti iwọ fi ohun iṣura rẹ ìkọkọ kún: awọn ọmọ wọn pọ̀n nwọn a si fi iyokù ini wọn silẹ fun awọn ọmọ-ọwọ́ wọn.
15. Bi o ṣe ti emi ni emi o ma wò oju rẹ li ododo: àworan rẹ yio tẹ mi lọrun nigbati mo ba jí.