Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 148:5-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Jẹ ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori ti on paṣẹ, a si da wọn.

6. O si fi idi wọn mulẹ lai ati lailai; o si ti ṣe ilana kan ti kì yio kọja.

7. Ẹ yìn Oluwa lati aiye wá, ẹnyin erinmi, ati gbogbo ibu-omi;

8. Iná ati yinyin òjo-didì ati ikũku; ìji mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ;

9. Ẹnyin òke nla, ati gbogbo òke kekere; igi eleso, ati gbogbo igi Kedari;

10. Ẹranko, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin; ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ́ ti nfò;

11. Awọn ọba aiye, ati gbogbo enia; ọmọ-alade, ati gbogbo onidajọ aiye;

12. Awọn ọdọmọkunrin ati awọn wundia, awọn arugbo enia ati awọn ọmọde;

13. Ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori orukọ rẹ̀ nikan li o li ọlá; ogo rẹ̀ bori aiye on ọrun.

14. O si gbé iwo kan soke fun awọn enia rẹ̀, iyìn fun gbogbo enia mimọ́ rẹ̀; ani awọn ọmọ Israeli, awọn enia ti o sunmọ ọdọ rẹ̀. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Ka pipe ipin O. Daf 148