Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 139:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA, iwọ ti wadi mi, iwọ si ti mọ̀ mi.

2. Iwọ mọ̀ ijoko mi ati idide mi, iwọ mọ̀ iro mi li ọ̀na jijin rére.

3. Iwọ yi ipa ọ̀na mi ká ati ibulẹ mi, gbogbo ọ̀na mi si di mimọ̀ fun ọ.

4. Nitori ti kò si ọ̀rọ kan li ahọn mi, kiyesi i, Oluwa, iwọ mọ̀ ọ patapata.

5. Iwọ sé mi mọ lẹhin ati niwaju, iwọ si fi ọwọ rẹ le mi.

6. Iru ìmọ yi ṣe ohun iyanu fun mi jù; o ga, emi kò le mọ̀ ọ.

7. Nibo li emi o gbe lọ kuro lọwọ ẹmi rẹ? tabi nibo li emi o sárè kuro niwaju rẹ?

8. Bi emi ba gòke lọ si ọrun, iwọ wà nibẹ: bi emi ba si tẹ́ ẹni mi ni ipò okú, kiyesi i, iwọ wà nibẹ.

9. Emi iba mu iyẹ-apa owurọ, ki emi si lọ joko niha opin okun;

10. Ani nibẹ na li ọwọ rẹ yio fà mi, ọwọ ọtún rẹ yio si dì mi mu.

11. Bi mo ba wipe, Njẹ ki òkunkun ki o bò mi mọlẹ; ki imọlẹ ki o di oru yi mi ka.

12. Nitõtọ òkunkun kì iṣu lọdọ rẹ; ṣugbọn oru tàn imọlẹ bi ọsan: ati òkunkun ati ọsan, mejeji bakanna ni fun ọ.

13. Nitori iwọ li o dá ọkàn mi: iwọ li o bò mi mọlẹ ni inu iya mi.

14. Emi o yìn ọ; nitori tẹ̀ru-tẹ̀ru ati tiyanu-tiyanu li a dá mi: iyanu ni iṣẹ rẹ; eyinì li ọkàn mi si mọ̀ dajudaju.

Ka pipe ipin O. Daf 139