Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 104:23-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Enia jade lọ si iṣẹ rẹ̀ ati si lãla rẹ̀ titi di aṣalẹ.

24. Oluwa, iṣẹ rẹ ti pọ̀ to! ninu ọgbọ́n ni iwọ ṣe gbogbo wọn: aiye kún fun ẹ̀da rẹ.

25. Bẹ̃li okun yi ti o tobi, ti o si ni ibò, nibẹ ni ohun ainiye nrakò, ati ẹran kekere ati nla.

26. Nibẹ li ọkọ̀ nrìn: nibẹ ni lefiatani nì wà, ti iwọ da lati ma ṣe ariya ninu rẹ̀.

27. Gbogbo wọnyi li o duro tì ọ; ki iwọ ki o le ma fun wọn li onjẹ wọn li akokò wọn.

28. Eyi ti iwọ fi fun wọn ni nwọn nkó: iwọ ṣí ọwọ rẹ, a si fi ohun rere tẹ́ wọn lọrùn.

29. Iwọ pa oju rẹ mọ́, ara kò rọ̀ wọn: iwọ gbà ẹmi wọn, nwọn kú, nwọn si pada si erupẹ wọn.

30. Iwọ rán ẹmi rẹ jade, a si da wọn: iwọ si sọ oju ilẹ di ọtun.

31. Ogo Oluwa yio wà lailai: Oluwa yio yọ̀ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀.

32. O bojuwo aiye, o si warìrì: o fi ọwọ kàn òke, nwọn si ru ẹ̃fin.

33. Emi o ma kọrin si Oluwa nigbati mo wà lãye: emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun mi ni igba aiye mi.

34. Jẹ ki iṣaro mi ki o mu inu rẹ̀ dùn: emi o mã yọ̀ ninu Oluwa.

35. Jẹ ki awọn ẹlẹṣẹ ki o run kuro li aiye, ki awọn enia buburu ki o má si mọ. Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Ka pipe ipin O. Daf 104