Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 9:4-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli ki nwọn ki o ma pa ajọ irekọja mọ́:

5. Nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla, oṣù kini, li aṣalẹ ni ijù Sinai: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe.

6. Awọn ọkunrin kan wà ti nwọn ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́, nwọn kò si le ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ na: nwọn si wá siwaju Mose ati siwaju Aaroni li ọjọ́ na:

7. Awọn ọkunrin na si wi fun u pe, Awa ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́: nitori kili a o ṣe fàsẹhin ti awa ki o le mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ Israeli?

8. Mose si wi fun wọn pe, Ẹ duro na; ki emi ki o le gbọ́ aṣẹ ti OLUWA yio pa niti nyin.

9. OLUWA si sọ fun Mose pe,

10. Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ẹnikẹni ninu nyin, tabi ninu iran nyin, ba ti ipa okú di alaimọ́, tabi bi o ba wà li ọ̀na àjo jijìn rére, sibẹ̀ on o pa ajọ irekọja mọ́ fun OLUWA.

11. Li ọjọ́ kẹrinla oṣù keji li aṣalẹ ni ki nwọn ki o pa a mọ́; ki nwọn si fi àkara alaiwu jẹ ẹ ati ewebẹ kikorò:

12. Ki nwọn ki o máṣe kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀, bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fọ́ egungun rẹ̀ kan: gẹgẹ bi gbogbo ìlana irekọja ni ki nwọn ki o ṣe e.

13. Ṣugbọn ọkunrin na ti o mọ́ ti kò si sí li ọ̀na àjo, ti o si fàsẹhin lati pa irekọja mọ́, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀: nitoriti kò mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀, ọkunrin na yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

14. Bi alejò kan ba si nṣe atipo lọdọ nyin, ti o si nfẹ́ pa irekọja mọ́ fun OLUWA; gẹgẹ bi ìlana irekọja, ati gẹgẹ bi aṣẹ rẹ̀, ni ki o ṣe bẹ̃: ìlana kan ni ki ẹnyin ki o ní, ati fun alejò, ati fun ibilẹ.

15. Ati li ọjọ́ ti a gbé agọ́ ró awọsanma si bò agọ́ na, eyinì ni, agọ́ ẹrí: ati li alẹ o si hàn lori agọ́ na bi iná, titi o fi di owurọ̀.

Ka pipe ipin Num 9