Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 8:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pẹ,

2. Sọ fun Aaroni, ki o si wi fun u pe, Nigbati iwọ ba tàn fitila, ki fitila mejeje na ki o ma tàn imọlẹ lori ọpá-fitila.

3. Aaroni si ṣe bẹ̃; o tàn fitila wọnni lori ọpá-fitila na, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

4. Iṣẹ ọpá-fitila na yi si jẹ̀ ti wurà lilù; titi dé isalẹ rẹ̀, titi dé itanna rẹ̀, o jẹ́ iṣẹ lulù: gẹgẹ bi apẹrẹ ti OLUWA fihàn Mose, bẹ̃li o ṣe ọpá-fitila na.

5. OLUWA si sọ fun Mose pe,

6. Yọ awọn ọmọ Lefi kuro ninu awọn ọmọ Israeli, ki o si wẹ̀ wọn mọ́.

7. Bayi ni ki iwọ ki o si ṣe si wọn, lati wẹ̀ wọn mọ́; Wọn omi etutu si wọn lara, ki nwọn ki o si fá gbogbo ara wọn, ki nwọn ki o si fọ̀ aṣọ wọn, ki nwọn ki o si wẹ̀ ara wọn mọ́.

8. Ki nwọn ki o si mú ẹgbọrọ akọmalu kan pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ani iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati ẹgbọrọ akọmalu keji ni ki iwọ ki o mú fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.

9. Ki iwọ ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju agọ́ ajọ: ki iwọ ki o si pe gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli jọ pọ̀:

10. Ki iwọ ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA: ki awọn ọmọ Israeli ki o si fi ọwọ́ wọn lé awọn ọmọ Lefi.

11. Ki Aaroni ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA, bi ọrẹ fifì lati ọdọ awọn ọmọ Israeli wá, ki nwọn ki o le ma ṣe iṣẹ-ìsin OLUWA.

Ka pipe ipin Num 8