Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 6:14-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. On o si mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá fun OLUWA, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan alailabùkun fun ẹbọ sisun, ati abo ọdọ-agutan kan ọlọdún kan alailabùkun fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan alailabùkun fun ẹbọ alafia.

15. Ati agbọ̀n àkara alaiwu kan, àkara adidùn iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si, ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn.

16. Ki alufa ki o mú wọn wá siwaju OLUWA, ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ati ẹbọ sisun rẹ̀:

17. Ki o si ru àgbo na li ẹbọ alafia si OLUWA, pẹlu agbọ̀n àkara alaiwu: ki alufa pẹlu ki o si ru ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.

18. Ki Nasiri na ki o fá ori ìyasapakan rẹ̀ li ẹnu-ọ̀na agọ́ àjọ, ki o si mú irun ori ìyasapakan rẹ̀ ki o si fi i sinu iná ti mbẹ labẹ ẹbọ alafia na.

19. Ki alufa ki o si mú apá bibọ̀ àgbo na, ati àkara adidùn kan alaiwu kuro ninu agbọ̀n na, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan alaiwu, ki o si fi wọn lé ọwọ́ Nasiri na, lẹhin ìgba ti a fá irun ori ìyasapakan rẹ̀ tán:

20. Ki alufa ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: mimọ́ li eyi fun alufa na, pẹlu àiya fifì, ati itan agbesọsoke: lẹhin na Nasiri na le ma mu ọti-waini.

21. Eyi li ofin ti Nasiri ti o ṣe ileri, ati ti ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ si OLUWA fun ìyasapakan rẹ̀ li àika eyiti ọwọ́ on le tẹ̀: gẹgẹ bi ileri ti o ṣe, bẹ̃ni ki o ṣe nipa ofin ìyasapakan rẹ̀.

22. OLUWA si sọ fun Mose pe,

23. Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Bayi li ẹnyin o ma sure fun awọn ọmọ Israeli; ki ẹ ma wi fun wọn pe,

24. Ki OLUWA ki o busi i fun ọ, ki o si pa ọ mọ́:

25. Ki OLUWA ki o mu oju rẹ̀ mọlẹ si ọ lara, ki o si ṣãnu fun ọ:

26. Ki OLUWA ki o ma bojuwò ọ, ki o si ma fun ọ ni alafia.

27. Bayi ni nwọn o fi orukọ mi sara awọn ọmọ Israeli; emi o si busi i fun wọn.

Ka pipe ipin Num 6