Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 5:17-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ki alufa ki o si bù omi mimọ́ ninu ohun-èlo amọ̀ kan; ati ninu erupẹ ti mbẹ ni ilẹ agọ́ ni ki alufa ki o bù, ki o si fi i sinu omi na:

18. Ki alufa ki o si mu obinrin na duro niwaju OLUWA, ki o si ṣí ibori obinrin na, ki o si fi ẹbọ ohunjijẹ iranti na lé e li ọwọ́, ti iṣe ẹbọ ohunjijẹ owú: ati li ọwọ́ alufa ni omi kikorò ti imú egún wá yio wà.

19. Alufa na yio si mu u bura, yio si wi fun obinrin na pe, Bi ọkunrin kò ba bá ọ dàpọ, bi iwọ kò ba si yàsapakan si ìwa-aimọ́, labẹ ọkọ rẹ, ki iwọ ki o yege omi kikorò yi ti imú egún wá:

20. Ṣugbọn bi iwọ ba yapa, labẹ ọkọ rẹ, ti iwọ si di ẹni ibàjẹ́, ti ọkunrin miran si bá ọ dàpọ laiṣe ọkọ rẹ:

21. Nigbana ni ki alufa ki o mu ki obinrin na fi èpe bura, ki alufa ki o si wi fun obinrin na pe, Ki OLUWA ki o sọ ọ di ẹni egún, ati ẹni ifire ninu awọn enia rẹ, nigbati OLUWA ba mu itan rẹ rà, ti o si mu inu rẹ wú;

22. Ati omi yi ti nmú egún wá ki o wọ̀ inu rẹ lọ, lati mu inu rẹ wú, ati lati mu itan rẹ rà: ki obinrin na ki o si wipe, Amin, amin.

23. Ki alufa ki o si kọ egún yi sinu iwé, ki o si fi omi kikorò na wẹ̀ ẹ nù:

24. Ki o si jẹ ki obinrin na ki o mu omi kikorò na ti imú egún wá: omi na ti imú egún wá yio si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, a si di kikorò.

Ka pipe ipin Num 5