Alufa na yio si mu u bura, yio si wi fun obinrin na pe, Bi ọkunrin kò ba bá ọ dàpọ, bi iwọ kò ba si yàsapakan si ìwa-aimọ́, labẹ ọkọ rẹ, ki iwọ ki o yege omi kikorò yi ti imú egún wá: