Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 35:24-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Nigbana ni ki ijọ ki o ṣe idajọ lãrin ẹniti o pa enia ati agbẹsan ẹ̀jẹ na, gẹgẹ bi idajọ wọnyi:

25. Ki ijọ ki o si gbà ẹniti o pani li ọwọ́ agbẹsan ẹ̀jẹ, ki ijọ ki o si mú u pada lọ si ilu àbo rẹ̀, nibiti o ti sá si: ki o si ma gbé ibẹ̀ titi di ìgba ikú olori alufa, ti a fi oróro mimọ́ yàn.

26. Ṣugbọn bi apania na ba ṣèṣi jade lọ si opinlẹ ilu àbo rẹ̀, nibiti o ti sá si;

27. Ti agbẹsan ẹ̀jẹ na si ri i lẹhin opinlẹ ilu àbo rẹ̀, ti agbẹsan ẹ̀jẹ si pa apania na; on ki yio jẹbi ẹ̀jẹ:

28. Nitoripe on iba joko ninu ilu àbo rẹ̀ titi di ìgba ikú olori alufa: ati lẹhin ikú olori alufa ki apania na ki o pada lọ si ilẹ iní rẹ̀.

29. Ohun wọnyi ni o si jẹ́ ìlana idajọ fun nyin ni iraniran nyin ni ibujoko nyin gbogbo.

30. Ẹnikẹni ti o ba pa enia, lati ẹnu awọn ẹlẹri wá li a o pa apania na: ṣugbọn ẹlẹri kanṣoṣo ki yio jẹri si ẹnikan lati pa a.

31. Pẹlupẹlu ki ẹnyin ki o máṣe gbà ohun-irasilẹ fun ẹmi apania, ti o jẹbi ikú: ṣugbọn pipa ni ki a pa a.

32. Ki ẹnyin ki o má si ṣe gbà ohun-irasilẹ fun ẹniti o salọ si ilu àbo rẹ̀, pe ki on ki o tun pada lọ ijoko ni ilẹ na, titi di ìgba ikú alufa.

33. Ẹnyin kò si gbọdọ bà ilẹ na jẹ́ ninu eyiti ẹnyin ngbé: nitoripe ẹ̀jẹ ama bà ilẹ jẹ́: a kò si le ṣètutu fun ilẹ nitori ẹ̀je ti a ta sinu rẹ̀, bikoṣe nipa ẹ̀jẹ ẹniti o ta a.

34. Iwọ kò si gbọdọ sọ ilẹ na di alaimọ́, ninu eyiti ẹnyin o joko, ninu eyiti emi ngbé: nitori Emi JEHOFA ni ngbé inu awọn ọmọ Israeli.

Ka pipe ipin Num 35