Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 33:8-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Nwọn si ṣí kuro niwaju Hahirotu, nwọn si là ãrin okun já lọ si aginjù: nwọn si rìn ìrin ijọ́ mẹta li aginjù Etamu, nwọn si dó si Mara.

9. Nwọn si ṣí kuro ni Mara, nwọn si wá si Elimu: ni Elimu ni orisun omi mejila, ati ãdọrin igi ọpẹ wà; nwọn si dó sibẹ̀.

10. Nwọn si ṣí kuro ni Elimu, nwọn si dó si ẹba Okun Pupa.

11. Nwọn si ṣí kuro li Okun Pupa, nwọn si dó si aginjù Sini.

12. Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sini, nwọn si dó si Dofka.

13. Nwọn si ṣí kuro ni Dofka, nwọn si dó si Aluṣi.

14. Nwọn si ṣí kuro ni Aluṣi, nwọn si dó si Refidimu, nibiti omi kò gbé sí fun awọn enia na lati mu.

15. Nwọn si ṣí kuro ni Refidimu, nwọn si dó si aginjù Sinai.

16. Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sinai, nwọn si dó si Kibrotu-hattaafa.

Ka pipe ipin Num 33