Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 33:5-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Awọn ọmọ Israeli si ṣí kuro ni Ramesesi, nwọn si dó si Sukkotu.

6. Nwọn si ṣí kuro ni Sukkotu, nwọn si dó si Etamu, ti mbẹ leti aginjù.

7. Nwọn si ṣí kuro ni Etamu, nwọn si pada lọ si Pi-hahirotu, ti mbẹ niwaju Baali-sefoni: nwọn si dó siwaju Migdolu.

8. Nwọn si ṣí kuro niwaju Hahirotu, nwọn si là ãrin okun já lọ si aginjù: nwọn si rìn ìrin ijọ́ mẹta li aginjù Etamu, nwọn si dó si Mara.

9. Nwọn si ṣí kuro ni Mara, nwọn si wá si Elimu: ni Elimu ni orisun omi mejila, ati ãdọrin igi ọpẹ wà; nwọn si dó sibẹ̀.

10. Nwọn si ṣí kuro ni Elimu, nwọn si dó si ẹba Okun Pupa.

11. Nwọn si ṣí kuro li Okun Pupa, nwọn si dó si aginjù Sini.

12. Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sini, nwọn si dó si Dofka.

13. Nwọn si ṣí kuro ni Dofka, nwọn si dó si Aluṣi.

14. Nwọn si ṣí kuro ni Aluṣi, nwọn si dó si Refidimu, nibiti omi kò gbé sí fun awọn enia na lati mu.

15. Nwọn si ṣí kuro ni Refidimu, nwọn si dó si aginjù Sinai.

16. Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sinai, nwọn si dó si Kibrotu-hattaafa.

17. Nwọn si ṣí kuro ni Kibrotu-hattaafa, nwọn si dó si Haserotu.

18. Nwọn si ṣí kuro ni Haserotu, nwọn si dó si Ritma.

Ka pipe ipin Num 33