Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 33:49-56 Yorùbá Bibeli (YCE)

49. Nwọn si dó si ẹba Jordani, lati Beti-jeṣimotu titi dé Abeli-ṣittimu ni pẹtẹlẹ̀ Moabu.

50. OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe,

51. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke odò Jordani si ilẹ Kenaani:

52. Nigbana ni ki ẹnyin ki o lé gbogbo awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; ki ẹnyin si run gbogbo aworán wọn, ki ẹnyin si run gbogbo ere didà wọn, ki ẹnyin si wó gbogbo ibi giga wọn palẹ:

53. Ki ẹnyin ki o si gbà ilẹ na, ki ẹnyin ki o si ma gbé inu rẹ̀: nitoripe mo ti fi ilẹ na fun nyin lati ní i.

54. Ki ẹnyin ki o si fi keké pín ilẹ na ni iní fun awọn idile nyin; fun ọ̀pọ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun diẹ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní diẹ fun: ki ilẹ-iní olukuluku ki o jẹ́ ibiti keké rẹ̀ ba bọ́ si; gẹgẹ bi ẹ̀ya awọn baba nyin ni ki ẹnyin ki o ní i.

55. Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba lé awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; yio si ṣe, awọn ti ẹnyin jẹ ki o kù ninu wọn yio di ẹgún si oju nyin, ati ẹgún si nyin ni ìha, nwọn o si ma yọ nyin lẹnu ni ilẹ na, ninu eyiti ẹnyin ngbé.

56. Yio si ṣe, bi emi ti rò lati ṣe si wọn, bẹ̃ni emi o ṣe si nyin.

Ka pipe ipin Num 33