Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 33:43-56 Yorùbá Bibeli (YCE)

43. Nwọn si ṣí kuro ni Punoni, nwọn si dó si Obotu.

44. Nwọn si ṣí kuro ni Obotu, nwọn si dó si Iye-abarimu, li àgbegbe Moabu.

45. Nwọn si ṣí kuro ni Iyimu, nwọn si dó si Dibon-gadi.

46. Nwọn si ṣí kuro ni Dibon-gadi, nwọn si dó si Almon-diblataimu.

47. Nwọn si ṣí kuro ni Almon-diblataimu, nwọn si dó si òke Abarimu, niwaju Nebo.

48. Nwọn si ṣí kuro ni òke Abarimu, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko.

49. Nwọn si dó si ẹba Jordani, lati Beti-jeṣimotu titi dé Abeli-ṣittimu ni pẹtẹlẹ̀ Moabu.

50. OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe,

51. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke odò Jordani si ilẹ Kenaani:

52. Nigbana ni ki ẹnyin ki o lé gbogbo awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; ki ẹnyin si run gbogbo aworán wọn, ki ẹnyin si run gbogbo ere didà wọn, ki ẹnyin si wó gbogbo ibi giga wọn palẹ:

53. Ki ẹnyin ki o si gbà ilẹ na, ki ẹnyin ki o si ma gbé inu rẹ̀: nitoripe mo ti fi ilẹ na fun nyin lati ní i.

54. Ki ẹnyin ki o si fi keké pín ilẹ na ni iní fun awọn idile nyin; fun ọ̀pọ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun diẹ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní diẹ fun: ki ilẹ-iní olukuluku ki o jẹ́ ibiti keké rẹ̀ ba bọ́ si; gẹgẹ bi ẹ̀ya awọn baba nyin ni ki ẹnyin ki o ní i.

55. Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba lé awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; yio si ṣe, awọn ti ẹnyin jẹ ki o kù ninu wọn yio di ẹgún si oju nyin, ati ẹgún si nyin ni ìha, nwọn o si ma yọ nyin lẹnu ni ilẹ na, ninu eyiti ẹnyin ngbé.

56. Yio si ṣe, bi emi ti rò lati ṣe si wọn, bẹ̃ni emi o ṣe si nyin.

Ka pipe ipin Num 33