Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 31:12-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nwọn si kó igbẹsin, ati ohun-iní, ati ikogun na wá sọdọ Mose, ati Eleasari alufa, ati sọdọ ijọ awọn ọmọ Israeli, si ibudó ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, ti mbẹ lẹba Jordani leti Jeriko.

13. Ati Mose, ati Eleasari alufa, ati gbogbo awọn olori ijọ, jade lọ ipade wọn lẹhin ibudó.

14. Mose si binu si awọn olori ogun na, pẹlu awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati balogun ọrọrún, ti o ti ogun na bọ̀.

15. Mose si wi fun wọn pe, Ẹ da gbogbo awọn obinrin si?

16. Kiyesi i, nipaṣe ọ̀rọ Balaamu awọn wọnyi li o mu awọn ọmọ Israeli dẹ̀ṣẹ si OLUWA niti ọ̀ran Peori, ti àrun si fi wà ninu ijọ OLUWA.

17. Njẹ nitorina, ẹ pa gbogbo ọkunrin ninu awọn ọmọ wẹ́wẹ, ki ẹ si pa gbogbo awọn obinrin ti o ti mọ̀ ọkunrin nipa ibá dapọ̀.

18. Ṣugbọn gbogbo awọn ọmọbinrin kekeké ti nwọn kò mọ̀ ọkunrin nipa ibá dapọ̀, ni ki ẹnyin dasi fun ara nyin.

19. Ki ẹnyin ki o si duro lẹhin ibudó ni ijọ meje: ẹnikẹni ti o ba pa enia, ati ẹnikẹni ti o ba farakàn ẹniti a pa, ki ẹnyin si wẹ̀ ara nyin mọ́, ati ara awọn igbẹsin nyin ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje.

20. Ki ẹnyin si fọ̀ gbogbo aṣọ nyin mọ́, ati gbogbo ohun ti a fi awọ ṣe, ati ohun gbogbo iṣẹ irun ewurẹ, ati ohun gbogbo ti a fi igi ṣe.

21. Eleasari alufa si wi fun awọn ologun ti nwọn lọ si ogun na pe, Eyi ni ilana ofin ti OLUWA filelẹ li aṣẹ fun Mose.

22. Kìki wurà, ati fadakà, ati idẹ ati irin, ati tanganran, ati ojé,

23. Gbogbo ohun ti o le kọja ninu iná, ni ki ẹnyin ki o mu là iná já yio si di mimọ́; ṣugbọn a o fi omi ìyasapakan wẹ̀ ẹ mọ́: ati gbogbo ohun ti kò le kọja ninu iná ni ki a mu là inu omi.

24. Ki ẹnyin ki o si fọ̀ aṣọ nyin ni ijọ́ keje, ẹnyin o si di mimọ́, lẹhin eyinì li ẹnyin o si wá sinu ibudó.

25. OLUWA si sọ fun Mose pe,

Ka pipe ipin Num 31