Ki ẹnyin ki o si duro lẹhin ibudó ni ijọ meje: ẹnikẹni ti o ba pa enia, ati ẹnikẹni ti o ba farakàn ẹniti a pa, ki ẹnyin si wẹ̀ ara nyin mọ́, ati ara awọn igbẹsin nyin ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje.