Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 31:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe,

2. Gbẹsan awọn ọmọ Israeli lara awọn ara Midiani: lẹhin eyinì ni a o kó ọ jọ pẹlu awọn enia rẹ.

3. Mose si sọ fun awọn enia na pe, Ki ninu nyin ki o hamọra ogun, ki nwọn ki o si tọ̀ awọn ara Midiani lọ, ki nwọn ki o si gbẹsan OLUWA lara Midiani.

4. Ninu ẹ̀ya kọkan ẹgbẹrun enia, ni gbogbo ẹ̀ya Israeli, ni ki ẹnyin ki o rán lọ si ogun na.

5. Bẹ̃ni nwọn si yàn ninu awọn ẹgbẹgbẹrun enia Israeli, ẹgbẹrun enia ninu ẹ̀ya kọkan, ẹgba mẹfa enia ti o hamọra ogun.

6. Mose si rán wọn lọ si ogun na, ẹgbẹrun enia ninu ẹ̀ya kọkan, awọn ati Finehasi ọmọ Eleasari alufa si ogun na, ti on ti ohunèlo ibi-mimọ́, ati ipè wọnni li ọwọ́ rẹ̀ lati fun.

7. Nwón si bá awọn ara Midiani jà, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose; nwọn si pa gbogbo awọn ọkunrin.

8. Nwọn si pa awọn ọba Midiani, pẹlu awọn iyokù ti a pa; eyinì ni Efi, ati Rekemu, ati Suru, ati Huri, ati Reba, ọba Midiani marun: Balaamu ọmọ Beoru ni nwọn si fi idà pa.

9. Awọn ọmọ Israeli si mú gbogbo awọn obinrin Midiani ni igbẹsin, ati awọn ọmọ kekere wọn, nwọn si kó gbogbo ohunọ̀sin wọn, ati gbogbo agboẹran wọn, ati gbogbo ẹrù wọn.

10. Nwọn si fi iná kun gbogbo ilu wọn ninu eyiti nwọn ngbé, ati gbogbo ibudó wọn.

11. Nwọn si kó gbogbo ikogun wọn, ati gbogbo ohun-iní, ati enia ati ẹran.

Ka pipe ipin Num 31