Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 27:9-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Bi on kò ba si lí ọmọbinrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-ini rẹ̀ fun awọn arakunrin rẹ̀.

10. Bi on kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun awọn arakunrin baba rẹ̀:

11. Bi baba rẹ̀ kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun ibatan rẹ̀, ti o sunmọ ọ ni idile rẹ̀, on ni ki o jogún rẹ̀: yio si jasi ìlana idajọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

12. OLUWA si sọ fun Mose pe, Gùn ori òke Abarimu yi lọ, ki o si wò ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli.

13. Nigbati iwọ ba ri i tán, a o si kó iwọ jọ pẹlu awọn enia rẹ, gẹgẹ bi a ti kó Aaroni arakunrin rẹ jọ.

14. Nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi li aginjù Sini, ni ìja ijọ, lati yà mi simimọ́ ni ibi omi nì niwaju wọn. (Wọnyi li omi Meriba ni Kadeṣi li aginjù Sini.)

15. Mose si sọ fun OLUWA pe,

16. Jẹ ki OLUWA, Ọlọrun ẹmi gbogbo enia, ki o yàn ọkunrin kan sori ijọ,

17. Ti yio ma ṣaju wọn jade lọ, ti yio si ma ṣaju wọn wọle wá, ti yio si ma sìn wọn lọ, ti yio si ma mú wọn bọ̀; ki ijọ enia OLUWA ki o máṣe dabi agutan ti kò lí oluṣọ.

18. OLUWA si sọ fun Mose pe, Iwọ mú Joṣua ọmọ Nuni, ọkunrin ninu ẹniti ẹmi wà, ki o si fi ọwọ́ rẹ lé e lori;

19. Ki o si mu u duro niwaju Eleasari alufa, ati niwaju gbogbo ijọ; ki o si fi aṣẹ fun u li oju wọn.

Ka pipe ipin Num 27