Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 27:3-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Baba wa kú li aginjù, on kò si sí ninu ẹgbẹ awọn ti o kó ara wọn jọ pọ̀ si OLUWA ninu ẹgbẹ Kora: ṣugbọn o kú ninu ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀; kò si lí ọmọkunrin.

4. Ẽhaṣe ti orukọ, baba wa yio fi parẹ kuro ninu idile rẹ̀, nitoriti kò lí ọmọkunrin? Fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin baba wa.

5. Mose si mú ọ̀ran wọn wá siwaju OLUWA.

6. OLUWA si sọ fun Mose pe,

7. Awọn ọmọbinrin Selofehadi sọ rere: nitõtọ, fun wọn ni ilẹ-iní kan lãrin awọn arakunrin baba wọn; ki iwọ ki o si ṣe ki ilẹ-iní baba wọn ki o kọja sọdọ wọn.

8. Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ọkunrin kan ba kú, ti kò si lí ọmọkunrin, njẹ ki ẹnyin ki o ṣe ki ilẹ-iní rẹ̀ ki o kọja sọdọ ọmọbinrin rẹ̀.

9. Bi on kò ba si lí ọmọbinrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-ini rẹ̀ fun awọn arakunrin rẹ̀.

10. Bi on kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun awọn arakunrin baba rẹ̀:

11. Bi baba rẹ̀ kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun ibatan rẹ̀, ti o sunmọ ọ ni idile rẹ̀, on ni ki o jogún rẹ̀: yio si jasi ìlana idajọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

12. OLUWA si sọ fun Mose pe, Gùn ori òke Abarimu yi lọ, ki o si wò ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli.

Ka pipe ipin Num 27