Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 26:50-60 Yorùbá Bibeli (YCE)

50. Wọnyi ni idile ti Naftali gẹgẹ bi idile wọn: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le egbeje.

51. Wọnyi li a kà ninu awọn ọmọ Israeli, ọgbọ̀n ọkẹ, o le ẹgbẹsan o din ãdọrin.

52. OLUWA si sọ fun Mose pe,

53. Fun awọn wọnyi ni ki a pín ilẹ na ni iní gẹgẹ bi iye orukọ.

54. Fun awọn ti o pọ̀ ni ki iwọ ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun awọn ti o kére ni ki iwọ ki o fi diẹ fun: ki a fi ilẹ-iní olukuluku fun u gẹgẹ bi iye awọn ti a kà ninu rẹ̀.

55. Ṣugbọn kèké li a o fi pín ilẹ na: gẹgẹ bi orukọ ẹ̀ya awọn baba wọn ni ki nwọn ki o ní i.

56. Gẹgẹ bi kèké ni ki a pín ilẹ-iní na lãrin awọn pupọ̀ ati diẹ.

57. Wọnyi si li awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, gẹgẹ bi idile wọn: ti Gerṣoni, idile awọn ọmọ Gerṣoni: ti Kohati, idile awọn ọmọ Kohati: ti Merari, idile awọn ọmọ Merari.

58. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Lefi: idile awọn ọmọ Libni, idile awọn ọmọ Hebroni, idile awọn ọmọ Mali, idile awọn ọmọ Muṣi, idile awọn ọmọ Kora. Kohati si bi Amramu.

59. Orukọ aya Amramu a si ma jẹ́ Jokebedi, ọmọbinrin Lefi, ti iya rẹ̀ bi fun Lefi ni Egipti: on si bi Aaroni, ati Mose, ati Miriamu arabinrin wọn fun Amramu.

60. Ati fun Aaroni li a bi Nadabu ati Abihu, Eleasari ati Itamari.

Ka pipe ipin Num 26