Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 25:7-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nigbati Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufa ri i, o dide lãrin ijọ, o si mú ọ̀kọ kan li ọwọ́ rẹ̀;

8. O si tọ̀ ọkunrin Israeli na lọ ninu agọ́, o si fi gún awọn mejeji li agunyọ, ọkunrin Israeli na, ati obinrin na ni inu rẹ̀. Àrun si da lãrin awọn ọmọ Israeli.

9. Awọn ti o si kú ninu àrun na jẹ́ ẹgba mejila.

10. OLUWA si sọ fun Mose pe,

11. Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufa ti yi ibinu mi pada kuro lara awọn ọmọ Israeli, nipa itara rẹ̀ nitori mi lãrin wọn, ki emi ki o máṣe run awọn ọmọ Israeli ninu owú mi.

12. Nitorina wipe, Kiyesi i, emi fi majẹmu alafia mi fun u.

Ka pipe ipin Num 25