Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 25:11-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufa ti yi ibinu mi pada kuro lara awọn ọmọ Israeli, nipa itara rẹ̀ nitori mi lãrin wọn, ki emi ki o máṣe run awọn ọmọ Israeli ninu owú mi.

12. Nitorina wipe, Kiyesi i, emi fi majẹmu alafia mi fun u.

13. Yio jẹ́ tirẹ̀ ati ti irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ani majẹmu iṣẹ-alufa titi-aiye; nitoriti o ṣe itara fun Ọlọrun rẹ̀, o si ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli.

14. Njẹ orukọ ọkunrin Israeli na ti a pa, ani ti a pa pẹlu obinrin Midiani na, a ma jẹ́ Simri, ọmọ Salu, olori ile kan ninu awọn ọmọ Simeoni.

15. Orukọ obinrin Midiani na ti a pa a si ma jẹ́ Kosbi, ọmọbinrin Suru; ti iṣe olori awọn enia kan, ati ti ile kan ni Midiani.

16. OLUWA si sọ fun Mose pe,

17. Yọ awọn ara Midiani lẹnu, ki o si kọlù wọn.

18. Nitoriti nwọn fi ẹ̀tan wọn yọ nyin lẹnu, eyiti nwọn tàn nyin niti ọ̀ran Peori, ati niti ọ̀ran Kosbi, ọmọ ijoye Midiani kan, arabinrin wọn, ẹniti a pa li ọjọ́ àrun nì niti ọ̀ran Peori.

Ka pipe ipin Num 25