Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 24:12-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Balaamu si wi fun Balaki pe, Emi kò ti sọ fun awọn onṣẹ rẹ pẹlu ti iwọ rán si mi pe,

13. Bi Balaki tilẹ fẹ́ lati fi ile rẹ̀ ti o kún fun fadakà ati wurá fun mi, emi kò le rekọja ọ̀rọ OLUWA, lati ṣe rere tabi buburu lati inu ara mi wá; ṣugbọn eyiti OLUWA wi, eyina li emi o sọ?

14. Njẹ nisisiyi si kiyesi i, emi nlọ sọdọ awọn enia mi: wá, emi o si sọ fun ọ ohun ti awọn enia yi yio ṣe si awọn enia rẹ li ẹhin-ọla.

15. O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ ṣí nwi:

16. Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o si mọ̀ imọ̀ Ọga-Ogo, ti o ri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ si ṣí:

17. Emi ri i, ṣugbọn ki iṣe nisisiyi: emi si wò o, ṣugbọn kò sunmọtosi: irawọ kan yio ti inu Jakobu jade wá, ọpa-alade kan yio si ti inu Israeli dide, yio si kọlù awọn igun Moabu, yio si ṣẹ́ gbogbo awọn ọmọ irọkẹ̀kẹ.

18. Edomu yio si di iní, Seiri pẹlu yio si di iní, fun awọn ọtá rẹ̀; Israeli yio si ṣe iṣe-agbara.

19. Lati inu Jakobu li ẹniti yio ní ijọba yio ti jade wá, yio si run ẹniti o kù ninu ilunla.

Ka pipe ipin Num 24