Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 23:3-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Balaamu si wi fun Balaki pe, Duro tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ; bọya OLUWA yio wá pade mi: ohunkohun ti o si fihàn mi emi o wi fun ọ. O si lọ si ibi giga kan.

4. Ọlọrun si pade Balaamu: o si wi fun u pe, Emi ti pèse pẹpẹ meje silẹ, mo si ti fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.

5. OLUWA si fi ọ̀rọ si Balaamu li ẹnu, o si wipe, Pada tọ̀ Balaki lọ, bayi ni ki iwọ ki o si sọ.

6. O si pada tọ̀ ọ lọ, si kiyesi i, on duro tì ẹbọ sisun rẹ̀, on ati gbogbo awọn ijoye Moabu.

7. O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaki ọba Moabu mú mi lati Aramu wá, lati òke-nla ìla-õrún wá, wipe, Wá, fi Jakobu bú fun mi, si wá, ki o fi Israeli ré.

8. Emi o ti ṣe fibú, ẹniti Ọlọrun kò fibú? tabi emi o si ti ṣe firé, ẹniti OLUWA kò firé?

9. Nitoripe lati ori apata wọnni ni mo ri i, ati lati òke wọnni ni mo wò o: kiyesi i, awọn enia yi yio dágbé, a ki yio si kà wọn kún awọn orilẹ-ède.

10. Tali o le kà erupẹ Jakobu, ati iye idamẹrin Israeli? Jẹ ki emi ki o kú ikú olododo, ki igbẹhin mi ki o si dabi tirẹ̀!

11. Balaki si wi fun Balaamu pe, Kini iwọ nṣe si mi yi? mo mú ọ wá lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i, iwọ si sure fun wọn patapata.

12. On si dahùn o si wipe, Emi ha le ṣe aiṣọra lati sọ eyiti OLUWA fi si mi li ẹnu bi?

13. Balaki si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bá mi lọ si ibomiran, lati ibiti iwọ o le ri wọn; kìki apakan wọn ni iwọ o ri, iwọ ki yio si ri gbogbo wọn tán; ki o si fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ.

14. O si mú u wá si igbẹ Sofimu sori òke Pisga, o si mọ pẹpẹ meje, o si fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.

15. On si wi fun Balaki pe, Duro nihin tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ ipade OLUWA lọhùn yi.

16. OLUWA si pade Balaamu, o si fi ọ̀rọ si i li ẹnu, wipe, Tun pada tọ̀ Balaki lọ, ki o si wi bayi.

Ka pipe ipin Num 23