Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 23:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BALAAMU si wi fun Balaki pe, Mọ pẹpẹ meje fun mi nihin, ki o si pèse akọ-malu meje, ati àgbo meje fun mi nihin.

2. Balaki si ṣe bi Balaamu ti wi; ati Balaki ati Balaamu fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.

3. Balaamu si wi fun Balaki pe, Duro tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ; bọya OLUWA yio wá pade mi: ohunkohun ti o si fihàn mi emi o wi fun ọ. O si lọ si ibi giga kan.

4. Ọlọrun si pade Balaamu: o si wi fun u pe, Emi ti pèse pẹpẹ meje silẹ, mo si ti fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.

5. OLUWA si fi ọ̀rọ si Balaamu li ẹnu, o si wipe, Pada tọ̀ Balaki lọ, bayi ni ki iwọ ki o si sọ.

6. O si pada tọ̀ ọ lọ, si kiyesi i, on duro tì ẹbọ sisun rẹ̀, on ati gbogbo awọn ijoye Moabu.

7. O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaki ọba Moabu mú mi lati Aramu wá, lati òke-nla ìla-õrún wá, wipe, Wá, fi Jakobu bú fun mi, si wá, ki o fi Israeli ré.

Ka pipe ipin Num 23