Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 20:15-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Bi awọn baba wa ti sọkalẹ lọ si Egipti, ti awa si ti gbé Egipti ni ìgba pipẹ; awọn ara Egipti si ni wa lara, ati awọn baba wa:

16. Nigbati awa si kepè OLUWA, o gbọ́ ohùn wa, o si rán angeli kan, o si mú wa lati Egipti jade wá; si kiyesi i, awa mbẹ ni Kadeṣi, ilu kan ni ipinlẹ àgbegbe rẹ:

17. Jẹ ki awa ki o là ilẹ rẹ kọja lọ, awa bẹ̀ ọ: awa ki yio là inu oko rẹ, tabi inu ọgbà-àjara, bẹ̃li awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li awa o gbà, awa ki o yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ.

18. Edomu si wi fun u pe, Iwọ ki yio kọja lọdọ mi, ki emi ki o má ba jade si ọ ti emi ti idà.

19. Awọn ọmọ Israeli si wi fun u pe, Ọ̀na opópo ọba li awa o gbà: bi awa ba mu ninu omi rẹ, emi ati ẹran mi, njẹ emi o san owo rẹ̀: laiṣe ohun miran, ki nsá fi ẹsẹ̀ mi là ilẹ kọja.

20. O si wipe, Iwọ ki yio là ilẹ kọja. Edomu si mú ọ̀pọ enia jade tọ̀ ọ wá pẹlu ọwọ́ agbara.

21. Bẹ̃li Edomu kọ̀ lati fi ọ̀na fun Israeli li àgbegbe rẹ̀: Israeli si ṣẹri kuro lọdọ rẹ̀.

22. Awọn ọmọ Israeli, ani gbogbo ijọ si ṣí kuro ni Kadeṣi, nwọn si wá si òke Hori.

23. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni li òke Hori li àgbegbe ilẹ Edomu wipe,

24. A o kó Aaroni jọ pẹlu awọn enia rẹ̀: nitoripe on ki yio wọ̀ inu ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli, nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi, nibi omi Meriba.

25. Mú Aaroni ati Eleasari ọmọ rẹ̀, ki o si mú wọn wá si ori-òke Hori:

26. Ki o si bọ́ Aaroni li aṣọ rẹ̀, ki o si fi wọn wọ̀ Eleasari ọmọ rẹ̀: a o si kó Aaroni jọ pẹlu awọn enia rẹ̀, yio si kú nibẹ̀.

27. Mose si ṣe bi OLUWA ti fun u li aṣẹ: nwọn si gòke lọ si ori òke Hori li oju gbogbo ijọ.

Ka pipe ipin Num 20