Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 2:28-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹjọ.

29. Ati ẹ̀ya Naftali: Ahira ọmọ Enani yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Naftali:

30. Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje.

31. Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Dani, jẹ́ ẹgba mejidilọgọrin o le ẹgbẹjọ. Awọn ni yio ṣí kẹhin pẹlu ọpagun wọn.

32. Eyi li awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ile baba wọn: gbogbo awọn ti a kà ni ibudó gẹgẹ bi ogun wọn, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ o le egbejidilogun din ãdọta.

33. Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi li a kò kà mọ́ awọn ọmọ Israeli; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

34. Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose: bẹ̃ni nwọn si dó pẹlu ọpagun wọn, bẹ̃ni nwọn si nṣí, olukuluku nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn.

Ka pipe ipin Num 2