Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 18:18-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ki ẹran wọn ki o si jẹ́ tirẹ, bi àiya fifì, ati bi itan ọtún, ni yio jẹ́ tirẹ.

19. Gbogbo ẹbọ igbesọsoke ohun mimọ́ wọnni, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun OLUWA, ni mo ti fi fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: majẹmu iyọ̀ ni lailai niwaju OLUWA fun ọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ.

20. OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Iwọ ki yio ní iní ninu ilẹ wọn, bẹ̃ni iwọ ki yio ní ipín lãrin wọn: Emi ni ipín rẹ ati iní rẹ lãrin awọn ọmọ Israeli.

21. Si kiyesi i, emi si ti fi gbogbo idamẹwa ni Israeli fun awọn ọmọ Lefi ni iní, nitori iṣẹ-ìsin wọn ti nwọn nṣe, ani iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ.

22. Awọn ọmọ Israeli kò si gbọdọ sunmọ agọ́ ajọ, ki nwọn ki o má ba rù ẹ̀ṣẹ, ki nwọn má ba kú.

23. Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ, awọn ni yio si ma rù ẹ̀ṣẹ wọn: ìlana lailai ni ni iran-iran nyin, ati lãrin awọn ọmọ Israeli, nwọn kò gbọdọ ní ilẹ-iní.

24. Nitori idamẹwa awọn ọmọ Israeli, ti nwọn múwa li ẹbọ igbesọsoke fun OLUWA, ni mo ti fi fun awọn ọmọ Lefi lati ní: nitorina ni mo ṣe wi fun wọn pe, Nwọn kò gbọdọ ní ilẹ-iní lãrin awọn ọmọ Israeli.

25. OLUWA si sọ fun Mose pe,

26. Si sọ fun awọn ọmọ Lefi, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba ngbà idamẹwa ti mo ti fi fun nyin ni ilẹiní nyin lọwọ awọn ọmọ Israeli, nigbana ni ki ẹnyin ki o mú ẹbọ igbesọsoke ninu rẹ̀ wá fun OLUWA, idamẹwa ninu idamẹwa na.

27. A o si kà ẹbọ igbesọsoke nyin yi si nyin, bi ẹnipe ọkà lati ilẹ ipakà wá, ati bi ọti lati ibi ifunti wá.

28. Bayi li ẹnyin pẹlu yio ma mú ẹbọ igbesọsoke wá fun OLUWA ninu gbogbo idamẹwa nyin, ti ẹnyin ngbà lọwọ awọn ọmọ Israeli; ki ẹnyin ki o si mú ẹbọ igbesọsoke OLUWA ninu rẹ̀ tọ̀ Aaroni alufa wá.

29. Ninu gbogbo ẹ̀bun nyin ni ki ẹnyin ki o si mú gbogbo ẹbọ igbesọsoke OLUWA wá, ninu gbogbo eyiti o dara, ani eyiti a yàsimimọ́ ninu rẹ̀.

30. Nitorina ki iwọ ki o wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba fi eyiti o dara ninu rẹ̀ ṣe ẹbọ igbesọsoke, nigbana ni ki a kà a fun awọn ọmọ Lefi bi ọkà ilẹ-ipakà, ati bi ibisi ibi-ifunti.

31. Ẹnyin o si jẹ ẹ ni ibi gbogbo, ati ẹnyin ati awọn ara ile nyin: nitoripe ère nyin ni fun iṣẹ-ìsin nyin ninu agọ́ ajọ.

32. Ẹnyin ki yio si rù ẹ̀ṣẹ nitori rẹ̀, nigbati ẹnyin ba fi eyiti o dara ninu rẹ̀ ṣe ẹbọ igbesọsoke: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ bà ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli jẹ́, ki ẹnyin ki o má ba kú.

Ka pipe ipin Num 18