Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 16:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ Kora, ọmọ Ishari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ati Datani on Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ati On, ọmọ Peleti, awọn ọmọ Reubeni, dìmọ:

2. Nwọn si dide niwaju Mose, pẹlu ãdọtalerugba ọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, ijoye ninu ijọ, awọn olorukọ ninu ajọ, awọn ọkunrin olokikí:

3. Nwọn si kó ara wọn jọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni, nwọn si wi fun wọn pe, O tó gẹ, nitoripe gbogbo ijọ li o jẹ́ mimọ́, olukuluku wọn, OLUWA si mbẹ lãrin wọn: nitori kili ẹnyin ha ṣe ngbé ara nyin ga jù ijọ OLUWA lọ?

4. Nigbati Mose gbọ́, o doju rẹ̀ bolẹ:

5. O si sọ fun Kora ati fun gbogbo ẹgbẹ rẹ̀ pe, Li ọla OLUWA yio fi ẹniti iṣe tirẹ̀ hàn, ati ẹniti o mọ́; yio si mu u sunmọ ọdọ rẹ̀: ani ẹniti on ba yàn ni yio mu sunmọ ọdọ rẹ̀.

6. Ẹ ṣe eyi; Ẹ mú awo-turari, Kora, ati gbogbo ẹgbẹ rẹ̀;

7. Ki ẹ si fi iná sinu wọn, ki ẹ si fi turari sinu wọn niwaju OLUWA li ọla: yio si ṣe, ọkunrin ti OLUWA ba yàn, on ni ẹni mimọ́: o tó gẹ, ẹnyin ọmọ Lefi.

8. Mose si wi fun Kora pe, Emi bẹ̀ nyin, ẹnyin ọmọ Lefi, ẹ gbọ́:

9. Ohun kekere ha ni li oju nyin, ti Ọlọrun Israeli yà nyin kuro ninu ijọ Israeli, lati mú nyin sunmọ ọdọ ara rẹ̀ lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ OLUWA, ati lati ma duro niwaju ijọ lati ma ṣe iranṣẹ fun wọn;

10. O si mú iwọ sunmọ ọdọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ gbogbo, awọn ọmọ Lefi pẹlu rẹ; ẹnyin si nwá iṣẹ-alufa pẹlu?

11. Nitorina, iwọ ati gbogbo ẹgbẹ rẹ kójọ pọ̀ si OLUWA: ati kini Aaroni, ti ẹnyin nkùn si i?

12. Mose si ranṣẹ pè Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu: nwọn si wipe, Awa ki yio gòke wá:

Ka pipe ipin Num 16