Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 14:32-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Ṣugbọn ẹnyin, okú nyin yio ṣubu li aginjú yi.

33. Awọn ọmọ nyin yio si ma rìn kiri li aginjù li ogoji ọdún, nwọn o si ma rù ìwa-àgbere nyin, titi okú nyin yio fi ṣòfo tán li aginjù.

34. Gẹgẹ bi iye ọjọ́ ti ẹnyin fi rìn ilẹ na wò, ani ogoji ọjọ́, ọjọ́ kan fun ọdún kan, li ẹnyin o rù ẹ̀ṣẹ nyin, ani ogoji ọdún, ẹnyin o si mọ̀ ibà ileri mi jẹ́.

35. Emi OLUWA ti sọ, Emi o ṣe e nitõtọ si gbogbo ijọ buburu yi, ti nwọn kójọ pọ̀ si mi: li aginjù yi ni nwọn o run, nibẹ̀ ni nwọn o si kú si.

36. Ati awọn ọkunrin na ti Mose rán lọ lati rìn ilẹ na wò, ti nwọn pada, ti nwọn si mu gbogbo ijọ kùn si i, ni mimú ìhin buburu ilẹ na wá,

37. Ani awọn ọkunrin na ti o mú ìhin buburu ilẹ na wá, nwọn ti ipa àrun kú niwaju OLUWA.

38. Ṣugbọn Joṣua ọmọ Nuni, ati Kalebu ọmọ Jefunne, ninu awọn ọkunrin na ti o rìn ilẹ na lọ, wà lãye.

39. Mose si sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli: awọn enia na si kãnu gidigidi.

40. Nwọn si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si gùn ori òke nì lọ, wipe, Kiyesi i, awa niyi, awa o si gòke lọ si ibiti OLUWA ti ṣe ileri: nitoripe awa ti ṣẹ̀.

41. Mose si wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nre aṣẹ OLUWA kọja? kì yio sa gbè nyin.

42. Ẹ máṣe gòke lọ, nitoriti OLUWA kò sí lãrin nyin, ki a má ba lù nyin bolẹ niwaju awọn ọtá nyin.

43. Nitoriti awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani mbẹ niwaju nyin, ẹnyin o si ti ipa idà ṣubu: nitoriti ẹnyin ti yipada kuro lẹhin OLUWA, nitorina OLUWA ki yio si pẹlu nyin.

44. Ṣugbọn nwọn fi igberaga gòke lọ sori òke na: ṣugbọn apoti ẹrí OLUWA, ati Mose, kò jade kuro ni ibudò.

Ka pipe ipin Num 14