Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 1:13-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ti Aṣeri; Pagieli ọmọ Okanri.

14. Ti Gadi; Eliasafu ọmọ Deueli.

15. Ti Naftali; Ahira ọmọ Enani.

16. Wọnyi li awọn ti a yàn ninu ijọ, olori ẹ̀ya awọn baba wọn, awọn olori ẹgbẹgbẹrun ni Israeli.

17. Ati Mose ati Aaroni mú awọn ọkunrin wọnyi ti a pè li orukọ:

18. Nwọn si pè gbogbo ijọ enia pọ̀ li ọjọ́ kini oṣù keji, nwọn si pìtan iran wọn gẹgẹ bi idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, nipa ori wọn.

19. Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li o si kaye wọn ni ijù Sinai.

20. Ati awọn ọmọ Reubeni, akọ́bi Israeli, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, nipa ori wọn, gbogbo ọkunrin lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

Ka pipe ipin Num 1