Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 6:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Iwọ pẹlu si ti yan awọn woli lati kede rẹ ni Jerusalemu wipe, Ọba wà ni Juda: nisisiyi ni a o si rò o fun ọba gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Njẹ wá nisisiyi, ki a jọ gbimọ̀ pọ̀.

8. Nigbana ni mo ranṣẹ si i wipe, A kò ṣe iru eyi, ti iwọ sọ, ṣugbọn iwọ rò wọn li ọkàn ara rẹ ni.

9. Nitori gbogbo wọn mu wa bẹ̀ru, wipe, Ọwọ wọn yio rọ ninu iṣẹ na, ki a má le ṣe e. Njẹ nisisiyi, Ọlọrun, mu ọwọ mi le.

10. Mo si wá si ile Ṣemaiah ọmọ Delaiah ọmọ Mehetabeeli, ti a há mọ, o si wipe, Jẹ ki a pejọ ni ile Ọlọrun ni inu tempili ki a si tì ilẹkùn tempili; nitori nwọn o wá lati pa ọ; nitõtọ, li oru ni nwọn o wá lati pa ọ.

11. Mo si wipe, Enia bi emi a ma sa? Tali o si dabi emi, ti o jẹ wọ inu tempili lọ lati gba ẹmi rẹ̀ là? Emi kì yio wọ̀ ọ lọ.

12. Sa kiyesi i, mo woye pe, Ọlọrun kò rán a, ṣugbọn pe, o nsọ asọtẹlẹ yi si mi: nitori Tobiah ati Sanballati ti bẹ̀ ẹ li ọ̀wẹ.

13. Nitorina li o ṣe bẹ̀ ẹ li ọ̀wẹ, ki emi ba foya, ki emi ṣe bẹ̃, ki emi si ṣẹ̀, ki nwọn le ri ihìn buburu rò, ki nwọn le kẹgàn mi.

14. Ọlọrun mi, rò ti Tobiah ati Sanballati gẹgẹ bi iṣẹ wọn wọnyi, ati ti Noadiah, woli obinrin, ati awọn woli iyokù ti nwọn fẹ mu mi bẹ̀ru,

Ka pipe ipin Neh 6