Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 6:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O SI ṣe, nigbati Sanballati, ati Tobiah, ati Geṣemu, ara Arabia, ati awọn ọta wa iyokù, gbọ́ pe, mo ti mọ odi na, ati pe, kò kù ibi yiya kan ninu rẹ̀, (bi emi kò tilẹ iti gbe ilẹkùn wọnni ro ni ibode li akoko na;)

2. Ni Sanballati ati Geṣemu ranṣẹ si mi, wipe, Wá, jẹ ki a jọ pade ninu ọkan ninu awọn ileto ni pẹtẹlẹ Ono. Ṣugbọn nwọn ngbero ati ṣe mi ni ibi.

3. Mo si ran onṣẹ si wọn pe, Emi nṣe iṣẹ nla kan, emi kò le sọkalẹ wá: ẽṣe ti iṣẹ na yio fi duro nigbati mo ba fi i silẹ, ti mo ba si sọkalẹ tọ̀ nyin wá?

4. Sibẹ nwọn ranṣẹ si mi nigba mẹrin bayi; mo si da wọn lohùn bakanna.

5. Nigbana ni Sanballati rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ si mi bakanna nigba karun ti on ti iwe ṣíṣi lọwọ rẹ̀.

6. Ninu rẹ̀ li a kọ pe, A nrohin lãrin awọn keferi, Gaṣimu si wi pe, iwọ ati awọn ara Juda rò lati ṣọ̀tẹ: nitori idi eyi ni iwọ ṣe mọ odi na, ki iwọ le jẹ ọba wọn, gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi.

7. Iwọ pẹlu si ti yan awọn woli lati kede rẹ ni Jerusalemu wipe, Ọba wà ni Juda: nisisiyi ni a o si rò o fun ọba gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Njẹ wá nisisiyi, ki a jọ gbimọ̀ pọ̀.

8. Nigbana ni mo ranṣẹ si i wipe, A kò ṣe iru eyi, ti iwọ sọ, ṣugbọn iwọ rò wọn li ọkàn ara rẹ ni.

9. Nitori gbogbo wọn mu wa bẹ̀ru, wipe, Ọwọ wọn yio rọ ninu iṣẹ na, ki a má le ṣe e. Njẹ nisisiyi, Ọlọrun, mu ọwọ mi le.

10. Mo si wá si ile Ṣemaiah ọmọ Delaiah ọmọ Mehetabeeli, ti a há mọ, o si wipe, Jẹ ki a pejọ ni ile Ọlọrun ni inu tempili ki a si tì ilẹkùn tempili; nitori nwọn o wá lati pa ọ; nitõtọ, li oru ni nwọn o wá lati pa ọ.

11. Mo si wipe, Enia bi emi a ma sa? Tali o si dabi emi, ti o jẹ wọ inu tempili lọ lati gba ẹmi rẹ̀ là? Emi kì yio wọ̀ ọ lọ.

Ka pipe ipin Neh 6