Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 12:41-47 Yorùbá Bibeli (YCE)

41. Ati awọn alufa: Eliakimu, Maaseiah, Miniamini Mikaiah, Elioenai, Sekariah, Hananiah mu fère lọwọ;

42. Ati Maaseiah, ati Ṣemaiah, ati Eleasari, ati Ussi, ati Jehohanani, ati Malkijah, ati Elamu, ati Eseri, awọn akọrin kọrin soke, pẹlu Jesrahiah alabojuto.

43. Li ọjọ na pẹlu nwọn ṣe irubọ nla, nwọn si yọ̀ nitori Ọlọrun ti mu wọn yọ̀ ayọ̀ nla, aya wọn ati awọn ọmọde yọ̀ pẹlu, tobẹ̃ ti a si gbọ́ ayọ̀ Jerusalemu li okere reré.

44. Li akoko na li a si yàn awọn kan ṣe olori yara iṣura, fun ọrẹ-ẹbọ, fun akọso, ati fun idamẹwa, lati ma ko ipin ti a yàn jọ lati oko ilu wọnni wá, ti ofin fun awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi: nitoriti Juda yọ̀ fun awọn ọmọ Lefi ti o duro.

45. Ati awọn akọrin, ati adèna npa ẹṣọ Ọlọrun wọn mọ, ati ẹṣọ iwẹnumọ́, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi; ati ti Solomoni ọmọ rẹ̀.

46. Nitori li ọjọ Dafidi ati Asafu nigbani awọn olori awọn akọrin wà, ati orin iyìn, ati ọpẹ fun Ọlọrun.

47. Gbogbo Israeli li ọjọ Serubbabeli, ati li ọjọ Nehemiah si fi ipin awọn akọrin, ati ti awọn adèna fun wọn olukuluku ni ipin tirẹ̀ li ojojumọ, nwọn si ya ohun mimọ́ awọn ọmọ Lefi si ọ̀tọ, awọn ọmọ Lefi si yà wọn si ọ̀tọ fun awọn ọmọ Aaroni.

Ka pipe ipin Neh 12