Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 12:24-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Awọn olori awọn ọmọ Lefi si ni Haṣabiah, Ṣerebiah, ati Jeṣua ọmọ Kadmieli, pẹlu awọn arakunrin wọn kọju si ara wọn, lati yìn ati lati dupẹ, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi enia Ọlọrun, li ẹgbẹgbẹ ẹṣọ.

25. Mattaniah, ati Bakbukiah, Obadiah, Meṣullamu, Talmoni, Akkubu, jẹ adèna lati ma ṣọ ìloro ẹnu-ọ̀na.

26. Wọnyi wà li ọjọ Joiakimu, ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati li ọjọ Nehemiah bãlẹ, ati Esra alufa, ti iṣe akọwe.

27. Ati nigba yiya odi Jerusalemu si mimọ́, nwọn wá awọn ọmọ Lefi kiri ninu gbogbo ibugbe wọn, lati mu wọn wá si Jerusalemu lati fi ayọ̀ ṣe iyà si mimọ́ na pẹlu idupẹ ati orin, pẹlu simbali, psalteri, ati pẹlu dùru.

28. Awọn ọmọ awọn akọrin si ko ara wọn jọ lati pẹ̀tẹlẹ yi Jerusalemu ka, ati lati ileto Netofati wá;

Ka pipe ipin Neh 12