Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nah 3:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EGBE ni fun ilu ẹjẹ̀ nì! gbogbo rẹ̀ kun fun eké, ati olè, ijẹ kò kuro;

2. Ariwo pàṣan, ati ariwo kikùn kẹkẹ́, ati ti ijọ awọn ẹṣin, ati ti fifò kẹkẹ́.

3. Ẹlẹṣin ti gbe idà rẹ̀ ti nkọ màna, ati ọkọ̀ rẹ̀ ti ndán yànran si oke: ọ̀pọlọpọ si li awọn ẹniti a pa, ati ọ̀pọlọpọ okú; okú kò si ni opin; nwọn nkọsẹ̀ li ara okú wọn wọnni:

4. Nitori ọ̀pọlọpọ awọn panṣagà àgbere ti o roju rere gbà, iya ajẹ ti o ntà awọn orilẹ-ède nipasẹ̀ panṣaga rẹ̀, ati idile nipasẹ̀ ajẹ rẹ̀.

5. Kiyesi i, emi dojukọ́ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ká aṣọ itẹlẹ̀di rẹ li oju rẹ, emi o si fi ihòho rẹ hàn awọn orilẹ-ède, ati itiju rẹ hàn awọn ilẹ̀ ọba.

6. Emi o da ẹgbin ti o ni irira si ọ lara, emi o si sọ ọ di alaimọ́, emi o si gbe ọ kalẹ bi ẹni ifiṣẹlẹyà.

7. Yio si ṣe pe, gbogbo awọn ti o wò ọ yio sa fun ọ, nwọn o si wipe, A ti fi Ninefe ṣòfo: tani yio kẹdùn rẹ̀? nibo ni emi o ti wá olutùnu fun ọ?

8. Iwọ ha sàn jù No-ammoni, eyiti o wà lãrin odò ti omi yika kiri, ti agbara rẹ̀ jẹ okun, ti odi rẹ̀ si ti inu okun jade wá?

9. Etiopia ati Egipti li agbara rẹ̀, kò si li opin; Puti ati Lubimu li awọn olùranlọwọ rẹ.

10. Sibẹ̀sibẹ̀ a kó o lọ, o lọ si oko-ẹrú: awọn ọmọ wẹ́wẹ rẹ̀ li a fi ṣánlẹ̀ pẹlu li ori ita gbogbo; nwọn si di ibò nitori awọn ọlọla rẹ̀ ọkunrin, gbogbo awọn ọlọla rẹ̀ li a si fi ẹwọ̀n dì.

11. Iwọ pẹlu o si yó ọti; a o si fi ọ pamọ, iwọ pẹlu o si ma ṣe afẹri ãbò nitori ti ọta na.

Ka pipe ipin Nah 3