orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mik 3 Yorùbá Bibeli (YCE)

Mika Bá Àwọn Olórí Israẹli Wí

1. EMI si wipe, Gbọ́, emi bẹ̀ nyin, ẹnyin olori ni Jakobu, ati ẹnyin alakoso ile Israeli; ti nyin kì iṣe lati mọ̀ idajọ bi?

2. Ẹnyin ti o korira ire, ti ẹ si fẹ ibi; ti ẹ já awọ-ara wọn kuro lara wọn, ati ẹran-ara wọn kuro li egungun wọn;

3. Awọn ẹniti o si jẹ ẹran-ara awọn enia mi pẹlu, ti nwọn si họ́ awọ-ara wọn kuro lara wọn, nwọn si fọ́ egungun wọn, nwọn si ke wọn wẹwẹ, bi ti ikòko, ati gẹgẹ bi ẹran ninu òdu.

4. Nigbana ni nwọn o kigbe pe Oluwa, ṣugbọn on kì yio gbọ́ ti wọn: on o tilẹ pa oju rẹ̀ mọ kuro lọdọ wọn li akoko na, gẹgẹ bi nwọn ti huwà alaifi ri ninu gbogbo iṣe wọn.

5. Bayi ni Oluwa wi niti awọn woli ti nṣì awọn enia mi li ọ̀na, ti nfi ehín wọn bù ni ṣán, ti o si nkigbe wipe, Alafia; on ẹniti kò fi nkan si wọn li ẹnu, awọn na si mura ogun si i.

6. Nitorina oru yio ru nyin, ti ẹnyin kì yio fi ri iran; òkunkun yio si kùn fun nyin, ti ẹnyin kì o fi le sọtẹlẹ; õrùn yio si wọ̀ lori awọn woli, ọjọ yio si ṣokùnkun lori wọn.

7. Oju yio si tì awọn ariran, awọn alasọtẹlẹ̀ na yio si dãmu: nitõtọ, gbogbo wọn o bò ete wọn: nitori idahùn kò si lati ọdọ Ọlọrun.

8. Ṣugbọn nitõtọ emi kún fun agbara nipa ẹmi Oluwa, ati fun idajọ, ati fun ipá, lati sọ irekọja Jakobu fun u, ati lati sọ ẹ̀ṣẹ Israeli fun u.

9. Gbọ́ eyi, emi bẹ̀ nyin, ẹnyin olori ile Jakobu; ati awọn alakoso ile Israeli, ti o korira idajọ, ti o si yi otitọ pada.

10. Ti o fi ẹjẹ kọ́ Sioni, ati Jerusalemu pẹlu iwà ẹ̀ṣẹ.

11. Awọn olori rẹ̀ nṣe idajọ nitori ère, awọn alufa rẹ̀ nkọ́ni fun ọyà, awọn woli rẹ̀ si nsọtẹlẹ fun owo: sibẹ ni nwọn o gbẹkẹle Oluwa, wipe, Oluwa kò ha wà lãrin wa? ibi kan kì yio ba wa.

12. Nitorina nitori nyin ni a o ṣe ro Sioni bi oko, Jerusalemu yio si di okìti, ati oke-nla ile bi ibi giga igbo.