orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mik 2 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ìjìyà fún Àwọn Tí Wọn ń Ni Àwọn Talaka Lára

1. EGBE ni fun awọn ti ngbìmọ aiṣedede, ti nṣiṣẹ ibi lori akete wọn! nigbati ojumọ́ mọ́ nwọn nṣe e, nitoripe o wà ni agbara ọwọ́ wọn.

2. Nwọn si nṣe ojukòkoro oko, nwọn si nfi ipá gbà a: ati ile, nwọn a si mu wọn lọ: nwọn si ni enia lara ati ile rẹ̀, ani enia ati ini rẹ̀.

3. Nitorina bayi ni Oluwa wi; Kiyesi i, emi ngbimọ̀ ibi si idile yi, ninu eyiti ọrùn nyin kì yio le yọ; bẹni ẹnyin kì yio fi igberaga lọ: nitori akokò ibi ni yi.

4. Li ọjọ na ni ẹnikan yio pa owe kan si nyin, yio si pohunrere-ẹkun kikorò pe, Ni kikó a kó wa tan? on ti pin iní enia mi: bawo ni o ti ṣe mu u kuro lọdọ mi! o ti pin oko wa fun awọn ti o yapa.

5. Nitorina iwọ kì yio ni ẹnikan ti yio ta okùn nipa ìbo ninu ijọ enia Oluwa.

6. Nwọn ni, ẹ máṣe sọtẹlẹ, nwọn o sọtẹlẹ, bi nwọn kò ba sọtẹlẹ bayi, itiju kì yio kuro.

7. Iwọ ẹniti anpe ni ile Jakobu, Ẹmi Oluwa ha bùkù bi? iṣe rẹ̀ ha ni wọnyi? ọ̀rọ mi kò ha nṣe rere fun ẹni ti nrin dẽde bi?

8. Ati nijelo awọn enia mi dide bi ọta si mi: ẹnyin ti bọ́ ẹ̀wu ati aṣọ ibora kuro lọdọ awọn ti nkọja li ailewu, bi awọn ẹniti o kọ̀ ogun silẹ.

9. Obinrin awọn enia mi li ẹnyin ti le jade kuro ninu ile wọn daradara; ẹnyin ti gbà ogo mi kuro lọwọ awọn ọmọ wọn lailai.

10. Ẹ dide, ki ẹ si ma lọ; nitoripe eyi kì iṣe ibi isimi: nitoriti o jẹ alaimọ́, yio pa nyin run, ani iparun kikorò?

11. Bi enia kan ti nrin ninu ẹmi ati itanjẹ ba ṣeke, wipe, emi o sọ asọtẹlẹ̀ ti ọti-waini ati ọti-lile fun ọ; on ni o tilẹ ṣe woli awọn enia yi.

12. Ni kikó emi o kó nyin jọ, iwọ Jakobu, gbogbo nyin; ni gbigbá emi o gbá iyokù Israeli jọ; emi o si tò wọn jọ pọ̀ gẹgẹ bi agutan Bosra, gẹgẹ bi ọwọ́ ẹran ninu agbo wọn: nwọn o si pariwo nla nitori ọ̀pọlọpọ enia.

13. Ẹniti nfọ́ni ti dide niwaju wọn: nwọn ti fọ́, nwọn kọja lãrin bode, nwọn si ti jade lọ nipa rẹ̀: ọba wọn o si kọja lọ niwaju wọn, Oluwa ni yio si ṣe olori wọn.