Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mal 3:4-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nigbana ni ọrẹ Juda ati ti Jerusalemu yio wù Oluwa, gẹgẹ bi ti ọjọ igbãni, ati gẹgẹ bi ọdun atijọ.

5. Emi o si sunmọ nyin fun idajọ, emi o si ṣe ẹlẹri yiyara si awọn oṣó, ati si awọn panṣaga, ati si awọn abura eké, ati awọn ti o ni alagbaṣe lara ninu ọyà rẹ̀, ati opo, ati alainibaba, ati si ẹniti o nrẹ́ alejo jẹ, ti nwọn kò si bẹ̀ru mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

6. Nitori Emi li Oluwa, Emi kò yipada; nitorina li a kò ṣe run ẹnyin ọmọ Jakobu.

7. Lati ọjọ awọn baba nyin wá li ẹnyin tilẹ ti yapa kuro ni ilàna mi, ti ẹ kò si pa wọn mọ. Ẹ yipada si ọdọ mi, Emi o si yipada si ọdọ nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa o yipada?

8. Enia yio ha jà Ọlọrun li olè? ṣugbọn ẹnyin sa ti jà mi li olè. Ṣugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa fi jà ọ li olè? Nipa idamẹwa ati ọrẹ.

9. Riré li a o fi nyin ré: nitori ẹnyin ti jà mi li olè, ani gbogbo orilẹ-ède yi.

10. Ẹ mu gbogbo idamẹwa wá si ile iṣura, ki onjẹ ba le wà ni ile mi, ẹ si fi eyi dán mi wò nisisiyi, bi emi ki yio ba ṣi awọn ferese ọrun fun nyin, ki nsi tú ibukún jade fun nyin, tobẹ̃ ti ki yio si aye to lati gbà a.

11. Emi o si ba ajẹnirun wi nitori nyin, on kì o si run eso ilẹ nyin, bẹ̃ni àjara nyin kì o rẹ̀ dànu, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

12. Gbogbo orilẹ-ède ni yio si pè nyin li alabukún fun: nitori ẹnyin o jẹ ilẹ ti o wuni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

13. Ọ̀rọ nyin ti jẹ lile si mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ọ̀rọ kili awa sọ si ọ?

14. Ẹnyin ti wipe, Asan ni lati sìn Ọlọrun: anfani kili o si wà, ti awa ti pa ilàna rẹ̀ mọ, ti awa si ti rìn ni igbãwẹ̀ niwaju Oluwa awọn ọmọ-ogun?

15. Ṣugbọn nisisiyi awa pè agberaga li alabùkunfun; lõtọ awọn ti o nhùwa buburu npọ si i; lõtọ, awọn ti o dán Oluwa wò li a dá si.

Ka pipe ipin Mal 3