14. O si ṣìn ifun ati itan rẹ̀, o si sun wọn li ẹbọ sisun lori pẹpẹ.
15. O si mú ọrẹ-ẹbọ awọn enia wá, o si mú obukọ, ti iṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun awọn enia, o si pa a, o si fi i rubọ ẹ̀ṣẹ, bi ti iṣaju.
16. O si mú ẹbọ sisun wá, o si ru u gẹgẹ bi ìlana na.
17. O si mú ẹbọ ohunjijẹ wá, o si bù ikunwọ kan ninu rẹ̀, o si sun u lori pẹpẹ, pẹlu ẹbọ sisun owurọ̀.
18. O si pa akọmalu ati àgbo fun ẹbọ alafia, ti iṣe ti awọn enia; awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ na tọ̀ ọ wá, o si fi i wọ́n ori pẹpẹ yiká.
19. Ati ọrá inu akọmalu na ati ti inu àgbo na, ìru rẹ̀ ti o lọrá, ati eyiti o bò ifun, ati iwe, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ:
20. Nwọn si fi ọrá na lé ori igẹ̀ wọnni, o si sun ọrà na lori pẹpẹ.
21. Ati igẹ̀ na ati itan ọtún ni Aaroni fì li ẹbọ fifì niwaju OLUWA; bi Mose ti fi aṣẹ lelẹ.
22. Aaroni si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke si awọn enia, o si sure fun wọn; o si sọkalẹ kuro ni ibi irubọ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ẹbọ sisun, ati ẹbọ alafia.
23. Mose ati Aaroni si wọ̀ inu agọ́ ajọ, nwọn si jade, nwọn si sure fun awọn enia: ogo OLUWA si farahàn fun gbogbo enia.
24. Iná kan si ti ọdọ OLUWA jade wá, o si jó ẹbọ sisun ati ọrá ori pẹpẹ na; nigbati gbogbo awọn enia ri i, nwọn hó kùhu, nwọn si dojubolẹ.