Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 6:24-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. OLUWA si sọ fun Mose pe,

25. Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eyi li ofin ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ni ibi ti a gbé pa ẹbọ sisun, ni ki a si pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ niwaju OLUWA: mimọ́ julọ ni.

26. Alufa ti o ru u fun ẹ̀ṣẹ ni ki o jẹ ẹ: ni ibi mimọ́ kan ni ki a jẹ ẹ, ninu agbalá agọ́ ajọ.

27. Ohunkohun ti o ba kàn ẹran rẹ̀ yio di mimọ́: nigbati ẹ̀jẹ rẹ̀ ba si ta sara aṣọ kan, ki iwọ ki o si fọ̀ eyiti o ta si na ni ibi mimọ́ kan.

28. Ṣugbọn ohunèlo àmọ, ninu eyiti a gbé bọ̀ ọ on ni ki a fọ́; bi a ba si bọ̀ ọ ninu ìkoko idẹ, ki a si fọ̀ ọ, ki a si ṣìn i ninu omi.

29. Gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn alufa ni ki o jẹ ninu rẹ̀: mimọ́ julọ ni.

30. Kò si sí ẹbọ ẹ̀ṣẹ kan, ẹ̀jẹ eyiti a múwa sinu agọ́ ajọ, lati fi ṣètutu ni ibi mimọ́, ti a gbọdọ jẹ: sisun ni ki a sun u ninu iná.

Ka pipe ipin Lef 6