Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 5:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BI ẹnikan ba si ṣẹ̀, ti o si gbọ́ ohùn ibura, ti o si ṣe ẹlẹri, bi on ba ri tabi bi on ba mọ̀, ti kò ba wi, njẹ ki o rù aiṣedede rẹ̀.

2. Tabi bi ẹnikan ba farakàn ohun alaimọ́ kan, iba ṣe okú ẹranko alaimọ́, tabi okú ẹranọ̀sin alaimọ́, tabi okú ohun ti nrakò alaimọ́, ti o ba si pamọ́ fun u, on pẹlu yio si ṣe alaimọ́, yio si jẹbi:

3. Tabi bi o ba farakàn ohun aimọ́ ti enia, ohunkohun aimọ́ ti o wù ki o ṣe ti a fi sọ enia di elẽri, ti o ba si pamọ́ fun u; nigbati o ba mọ̀, nigbana ni on yio jẹbi:

4. Tabi bi ẹnikan ba bura, ti o nfi ète rẹ̀ sọ ati ṣe ibi, tabi ati ṣe rere, ohunkohun ti o wù ki o ṣe ti enia ba fi ibura sọ, ti o ba si pamọ́ fun u; nigbati o ba mọ̀, nigbana ni on yio jẹbi ọkan ninu ohun wọnyi:

5. Yio si ṣe, nigbati o ba jẹbi ọkan ninu ohun wọnyi, ki o jẹwọ pe on ti ṣẹ̀ li ohun na.

6. Ki o si mú ẹbọ ẹbi rẹ̀ wá fun OLUWA, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, abo lati inu agbo-ẹran wá, ọdọ-agutan tabi ọmọ ewurẹ kan, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

7. Bi kò ba si le mú ọdọ-agutan wá, njẹ ki o mú àdaba meji tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá fun ẹbọ ẹbi fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀; ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun.

8. Ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá, ẹniti yio tète rubọ eyiti iṣe ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti yio si mi i li ọrùn, ṣugbọn ki yio pín i meji:

9. Ki o si fi ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì wọ́n ìha pẹpẹ; ati ẹ̀jẹ iyokù ni ki a ro si isalẹ pẹpẹ na: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.

Ka pipe ipin Lef 5