Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 26:5-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ipakà nyin yio si dé ìgba ikore àjara, igba ikore àjara yio si dé ìgba ifunrugbìn: ẹnyin o si ma jẹ onjẹ nyin li ajẹyo, ẹ o si ma gbé ilẹ nyin li ailewu.

6. Emi o si fi alafia si ilẹ na, ẹnyin o si dubulẹ, kò si sí ẹniti yio dẹruba nyin: emi o si mu ki ẹranko buburu ki o dasẹ kuro ni ilẹ na, bẹ̃ni idà ki yio là ilẹ nyin já.

7. Ẹnyin o si lé awọn ọtá nyin, nwọn o si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin.

8. Marun ninu nyin yio si lé ọgọrun, ọgọrun ninu nyin yio si lé ẹgbarun: awọn ọtá nyin yio si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin.

9. Nitoriti emi o fi ojurere wò nyin, emi o si mu nyin bisi i, emi o si sọ nyin di pupọ̀, emi o si gbé majẹmu mi kalẹ pẹlu nyin.

10. Ẹnyin o si ma jẹ ohun isigbẹ, ẹnyin o si ma kó ohun ẹgbẹ jade nitori ohun titun.

11. Emi o si gbé ibugbé mi kalẹ lãrin nyin: ọkàn mi ki yio si korira nyin.

12. Emi o si ma rìn lãrin nyin, emi o si ma ṣe Ọlọrun nyin, ẹnyin o si ma ṣe enia mi.

13. Emi li OLUWA Ọlọrun nyin ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, ki ẹnyin ki o máṣe wà li ẹrú wọn; emi si ti dá ìde àjaga nyin, mo si mu nyin rìn lõrogangan.

14. Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti emi, ti ẹ kò si ṣe gbogbo ofin wọnyi;

15. Bi ẹnyin ba si gàn ìlana mi, tabi bi ọkàn nyin ba korira idajọ mi, tobẹ̃ ti ẹnyin ki yio fi ṣe gbogbo ofin mi, ṣugbọn ti ẹnyin dà majẹmu mi;

Ka pipe ipin Lef 26