Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 25:34-51 Yorùbá Bibeli (YCE)

34. Ṣugbọn ilẹ ẹba ilu wọn ni nwọn kò gbọdọ tà; nitoripe ilẹ-iní wọn ni titi aiye.

35. Ati bi arakunrin rẹ ba di talakà, ti ọwọ́ rẹ̀ ba si rẹlẹ lọdọ rẹ; njẹ ki iwọ ki o ràn a lọwọ; ibaṣe alejò, tabi atipo; ki on ki o le wà pẹlu rẹ.

36. Iwọ máṣe gbà elé lọwọ rẹ̀, tabi ẹdá; ṣugbọn bẹ̀ru Ọlọrun rẹ; ki arakunrin rẹ ki o le wà pẹlu rẹ.

37. Iwọ kò gbọdọ fi owo rẹ fun u li ẹdá, tabi ki o wín i li onjẹ rẹ fun asanlé.

38. Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, lati fi ilẹ Kenaani fun nyin, ati lati ma ṣe Ọlọrun nyin.

39. Ati bi arakunrin rẹ ti mba ọ gbé ba di talakà, ti o si tà ara rẹ̀ fun ọ; iwọ kò gbọdọ sìn i ni ìsin-ẹrú:

40. Bikoṣe bi alagbaṣe, ati bi atipo, ni ki o ma ba ọ gbé, ki o si ma sìn ọ titi di ọdún jubeli:

41. Nigbana ni ki o lọ kuro lọdọ rẹ, ati on ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ki o si pada lọ si idile rẹ̀, ati si ilẹ-iní awọn baba rẹ̀ ni ki o pada si.

42. Nitoripe iranṣẹ mi ni nwọn iṣe, ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá: a kò gbọdọ tà wọn bi ẹni tà ẹrú.

43. Iwọ kò gbọdọ fi irorò sìn i; ṣugbọn ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ.

44. Ati awọn ẹrú rẹ ọkunrin, ati awọn ẹrú rẹ obinrin, ti iwọ o ní; ki nwọn ki o jẹ́ ati inu awọn orilẹ-ède wá ti o yi nyin ká, ninu wọn ni ki ẹnyin ki o ma rà awọn ẹrú-ọkunrin ati awọn ẹrú-obinrin.

45. Pẹlupẹlu ninu awọn ọmọ alejò ti nṣe atipo pẹlu nyin, ninu wọn ni ki ẹnyin ki o rà, ati ninu awọn idile wọn ti mbẹ pẹlu nyin, ti nwọn bi ni ilẹ nyin: nwọn o si jẹ iní nyin.

46. Ẹnyin o si ma fi wọn jẹ ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin, lati ní wọn ni iní; ẹnyin o si ma sìn wọn lailai: ṣugbọn ninu awọn arakunrin nyin awọn ọmọ Israeli, ẹnikan kò gbọdọ fi irorò sìn ẹnikeji rẹ̀.

47. Ati bi alejò tabi atipo kan ba di ọlọrọ̀ lọdọ rẹ, ati arakunrin rẹ kan leti ọdọ rẹ̀ ba di talakà, ti o ba si tà ara rẹ̀ fun alejò tabi atipo na leti ọdọ rẹ, tabi fun ibatan idile alejò na:

48. Lẹhin igbati o tà ara rẹ̀ tán, a si tún le rà a pada; ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀ le rà a:

49. Ibaṣe arakunrin õbi rẹ̀, tabi ọmọ arakunrin õbi rẹ̀, le rà a, tabi ibatan rẹ̀ ninu idile rẹ̀ le rà a; tabi bi o ba di ọlọrọ̀, o le rà ara rẹ̀.

50. Ki o si ba ẹniti o rà a ṣìro lati ọdún ti o ti tà ara rẹ̀ fun u titi di ọdún jubeli: ki iye owo ìta rẹ̀ ki o si ri gẹgẹ bi iye ọdún, gẹgẹ bi ìgba alagbaṣe ni ki o ri fun u.

51. Bi ọdún rẹ̀ ba kù pupọ̀ sibẹ̀, gẹgẹ bi iye wọn ni ki o si san owo ìrasilẹ rẹ̀ pada ninu owo ti a fi rà a.

Ka pipe ipin Lef 25