Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 25:3-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ọdún mẹfa ni iwọ o fi gbìn oko rẹ, ọdún mẹfa ni iwọ o si fi rẹwọ ọgbà-ajara rẹ, ti iwọ o si kó eso rẹ̀ jọ;

4. Ṣugbọn ọdún keje ki o si jasi ìgba isimi fun ilẹ na, isimi fun OLUWA: iwọ kò gbọdọ gbìn oko rẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ rẹwọ ọgbà-àjara rẹ.

5. Eyiti o ba lalẹ̀ hù ninu ikore rẹ iwọ kò gbọdọ ká, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ká eso àjara rẹ ti iwọ kò rẹ́ lọwọ: nitoripe ọdún isimi ni fun ilẹ na.

6. Ọdún isimi ilẹ na yio si ma ṣe ohunjijẹ fun nyin; fun iwọ, ati fun iranṣẹ rẹ ọkunrin, ati fun iranṣẹ rẹ obinrin, ati fun alagbaṣe rẹ, ati fun alejò rẹ ti nṣe atipo lọdọ rẹ;

7. Ati fun ohunọ̀sin rẹ, ati fun ẹran ti mbẹ ni ilẹ rẹ, ni ki ibisi rẹ̀ gbogbo ki o ṣe onjẹ fun.

8. Ki iwọ ki o si kà ọdún isimi meje fun ara rẹ, ọdún meje ìgba meje; ati akokò ọdún isimi meje ni yio jẹ́ ọdún mọkandilãdọta fun ọ.

Ka pipe ipin Lef 25