Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 25:18-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Nitorina ki ẹnyin ki o ma ṣe ìlana mi, ki ẹ si ma pa ofin mi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn; ẹnyin o si ma gbé ilẹ na li ailewu.

19. Ilẹ na yio si ma mú ibisi rẹ̀ wá, ẹ o si ma jẹ ajẹyo, ẹ o si ma gbé inu rẹ̀ li ailewu.

20. Bi ẹnyin ba si wipe, Kili awa o ha ma jẹ li ọdún keje? sa wo o, awa kò gbọdọ gbìn, bẹ̃li awa kò gbọdọ kó ire wa:

21. Nigbana li emi o fi aṣẹ ibukún mi fun nyin li ọdún kẹfa, on o si so eso jade fun nyin fun ọdún mẹta.

22. Ẹnyin o si gbìn li ọdún kẹjọ, ẹnyin o si ma jẹ ninu eso lailai titi di ọdún kẹsan, titi eso rẹ̀ yio fi dé ni ẹnyin o ma jẹ ohun isigbẹ.

23. Ẹnyin kò gbọdọ tà ilẹ lailai; nitoripe ti emi ni ilẹ: nitoripe alejò ati atipo ni nyin lọdọ mi.

24. Ati ni gbogbo ilẹ-iní nyin ki ẹnyin ki o si ma ṣe ìrapada fun ilẹ.

25. Bi arakunrin rẹ ba di talakà, ti o ba si tà ninu ilẹ-iní rẹ̀, bi ẹnikan ninu awọn ibatan rẹ̀ ba si wá lati rà a, njẹ ki o rà eyiti arakunrin rẹ̀ ti tà pada.

26. Bi ọkunrin na kò ba ní ẹnikan ti yio rà a pada, ti on tikara rẹ̀ ti di olowo ti o ní to lati rà a pada;

27. Nigbana ni ki o kà ọdún ìta rẹ̀, ki o si mú elé owo rẹ̀ pada fun ẹniti o tà a fun, ki on ki o le pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀.

28. Ṣugbọn bi o ba ṣepe on kò le san a pada fun u, njẹ ki ohun ti o tà na ki o gbé ọwọ́ ẹniti o rà a titi di ọdún jubeli: yio si bọ́ ni jubeli, on o si pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀.

Ka pipe ipin Lef 25