Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 24:6-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ki iwọ ki o si tò wọn li ẹsẹ meji, mẹfa li ẹsẹ kan, lori tabili mimọ́ niwaju OLUWA.

7. Ki iwọ ki o si fi turari daradara sori ẹsẹ̀ kọkan ki o le wà lori ìṣu-àkara na fun iranti, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.

8. Li ọjọjọ́ isimi ni ki ẹ ma tun u tò niwaju OLUWA titi; gbigbà ni lọwọ awọn ọmọ Israeli nipa majẹmu titi aiye.

9. Ki o si ma jẹ́ ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ; ki nwọn ki o si ma jẹ ẹ ni ibi mimọ́ kan: nitoripe mimọ́ julọ ni fun u ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ìlana titilai.

10. Ati ọmọkunrin obinrin Israeli kan, ti baba rẹ̀ ṣe ara Egipti, o jade lọ ninu awọn ọmọ Israeli: ọmọkunrin obinrin Israeli yi ati ọkunrin Israeli kan si jà ni ibudó.

11. Eyi ọmọkunrin obinrin Israeli yi, sọ̀rọ buburu si Orukọ nì, o si fi bú: nwọn si mú u tọ̀ Mose wá. Orukọ iya rẹ̀ ama jẹ Ṣelomiti, ọmọbinrin Dibri, ti ẹ̀ya Dani.

12. Nwọn si ha a mọ́ ile-ìde, titi a o fi fi inu OLUWA hàn fun wọn.

13. OLUWA si sọ fun Mose pe,

14. Mú ẹniti o ṣe ifibu nì wá sẹhin ibudó; ki gbogbo awọn ti o si gbọ́ ọ ki o fi ọwọ́ wọn lé ori rẹ̀, ki gbogbo ijọ enia ki o le sọ ọ li okuta.

15. Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnikẹni ti o ba fi Ọlọrun rẹ̀ bú yio rù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Lef 24