Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 24:11-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Eyi ọmọkunrin obinrin Israeli yi, sọ̀rọ buburu si Orukọ nì, o si fi bú: nwọn si mú u tọ̀ Mose wá. Orukọ iya rẹ̀ ama jẹ Ṣelomiti, ọmọbinrin Dibri, ti ẹ̀ya Dani.

12. Nwọn si ha a mọ́ ile-ìde, titi a o fi fi inu OLUWA hàn fun wọn.

13. OLUWA si sọ fun Mose pe,

14. Mú ẹniti o ṣe ifibu nì wá sẹhin ibudó; ki gbogbo awọn ti o si gbọ́ ọ ki o fi ọwọ́ wọn lé ori rẹ̀, ki gbogbo ijọ enia ki o le sọ ọ li okuta.

15. Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnikẹni ti o ba fi Ọlọrun rẹ̀ bú yio rù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

16. Ati ẹniti o sọ̀rọ buburu si orukọ OLUWA nì, pipa ni ki a pa a: gbogbo ijọ enia ni ki o sọ ọ li okuta pa nitõtọ: ati alejò, ati ibilẹ, nigbati o ba sọ̀rọbuburu si orukọ OLUWA, pipa li a o pa a.

17. Ati ẹniti o ba gbà ẹmi enia, pipa li a o pa a:

18. Ẹniti o ba si lù ẹran kan pa, ki o san a pada: ẹmi fun ẹmi.

19. Bi ẹnikan ba si ṣe abùku kan si ara ẹnikeji rẹ̀; bi o ti ṣe, bẹ̃ni ki a ṣe si i;

20. Ẹ̀ya fun ẹ̀ya, oju fun oju, ehin fun ehin; bi on ti ṣe abùku si ara enia, bẹ̃ni ki a ṣe si i.

21. Ẹniti o ba si lù ẹran pa, ki o san a pada: ẹniti o ba si lù enia pa, a o pa a.

22. Irú ofin kan li ẹnyin o ní, gẹgẹ bi fun alejò bẹ̃ni fun ibilẹ: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

23. Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli, pe ki nwọn ki o mú ẹniti o ṣe ifibu nì jade lọ sẹhin ibudó, ki nwọn ki o si sọ ọ li okuta pa. Awọn ọmọ Israeli si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

Ka pipe ipin Lef 24